Isaiah 43

Olùgbàlà Israẹli kan ṣoṣo

1Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí
ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu
ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli:
“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
2Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
kò ní jó ọ;
ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
4Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
5Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá
èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
6Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’
Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’
Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
tí mo dá fún ògo mi,
tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”

8Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,
tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
9Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ
àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.
Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí
tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?
Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá
láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí
wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
10“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,
“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
11Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,
yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde
Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”

Àánú Ọlọ́run àti àìṣòdodo Israẹli

14Èyí ni ohun tí Olúwa
olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli;
“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli
láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,
gbogbo ará Babeli
nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,
Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”

16Èyí ni ohun tí Olúwa
Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun,
ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,
17ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,
àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,
wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,
wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:
18“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;
má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!
Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?
Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi
kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.

22“Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,
ìwọ Jakọbu,
àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi
ìwọ Israẹli.
23Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,
tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.
Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun
tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.

25“Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ
àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,
tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,
jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;
ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
27Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;
àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
28Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún
àti Israẹli fún ẹ̀gàn.
Copyright information for YorBMYO